D. O. Fagunwa: Aadota Odun Lehin Ti O Papoda
Ni ipari Egbewa Odun o le metala (2013) ni yoo pe aadota odun geere ti olukoni ati onkowe Yoruba atata, Oloye Daniel Fagunwa fi aye sile lojiji (Osu Kejila 1963). Nigba ti Fagunwa gbe Ogboju Ode Ninu Igbo Irunmale, iwe-onitan ti o koko ko, jade ni Eedegbewa Odun o le mejidinlogoji (1938), asa ikowe aroso ni ede Yoruba bere ni pataki, o si gbooro kaakiri ile Naijiria debii pe o tayo Yoruba nikan. Awon iwe yooku ti o ko ni Igbo Olodumare (Eedegbewa Odun o le mokandinlaadota, 1949), Ireke Onibudo (ninu odun kan naa, 1949), Irinkerindo Ninu Igbo Elegbeje (Eedegbewa Odun o le merinlelaadota, 1954), ati Adiitu Olodumare (Eedegbewa Odun o le mokanlelogota, 1961). Awon iwe-onitan maraarun ti Fagunwa ko layee re gbayi lopolopo, biotilejepe kope ti eyi ti o ko kehin jade ni odun 1961 ni o jade laye. Nigba ti yoo fi di Eedegbewa Odun o le marunlelogota (1965), a ti te Ogboju Ode jade ni eemerinlelogun, opolopo onkowe Yoruba ni o si ti ntele irufe ikowe irinajo-akikanju ti a mo Fagunwa si; onkowe Amos Tutuola naa si ngbe ona-ikowe naa laruge ledee Geesi; Wole Soyinka tun tumo Ogboju Ode si ede Geesi. Asa-ikowe to bere lati owo Fagunwa ti gbile nibi gbogbo, o nlo siwaju gidigidi, o si je ohun isipaya fun awon onise-ona ninu litireso, ere ori-itage, sinima, ati awon olorin. Nigba ti a se iwadi kehin, a rii pe meta ninu iwe-onitan Fagunwa ni won ti tumo si ede Geesi, awon gbenugbenu ko si dawo duro nipa atungbeyewo lorisirisi lori awon iwe-onitan naa.
Opo ninu awon gbenugbenu ti toka si ise-takuntakun ti Fagunwa gbe se nipa lilo ede Yoruba lona ti o bu kun ijinle ede naa, bo se je pe ninu ilo-ede lati owo onkowe yii ni ede naa ti ngberu sii. Oye yii si farape bi onkowe Fagunwa se lo awon iwe-onitan naa lati peri araa re bii omo Yoruba, omo Naijiria, omo adulawo ti o si laju si ihuwasi ti ode-oni. Ilo-ede lati fi se iperi ara-eni je okan ninu awon ohun-pataki lara ise onkowe naa; a tun rii pe awon iwe-onitan re fi agbekale isowo-kowe han gedegede ni eyi ti o koja ohun akawe isele ojoojumo.
Nje kini ipa ti ise Fagunwa ko ninu ilosiwaju iwe-kiko kaakiri ile adulawo? Ona wo ni awon onkowe miiran, yala won je gbenugbenu, alapileko tabi olutumo, ngba lati jeki ina ise naa jo ajoroke, biotilejepe awon iwe-onitan naa ko fi bee po? Ipinnu wa ni lati pe apejo awon omowe kariaye ti won yoo parapo se agbeyewo titun nipa gbogbo iwe ti oloogbe naa ko sile. A mo pe ise-owo Fagunwa nii se pelu asa ati ise, oro ikowe-sona, ati oro iselu, sugbon ero wa nipe awon omowe, gbenugbenu, ati awon onkowe yoo fi okan si hulehule awon iwe-onitan maraarun, boya ni ede Yoruba tabi awon ti a ti tumo s’ede miiran. A si tun lero pe apejo yii yoo je ibere ise-iwadi arojinle, eyi ti yoo se okunfa ifinukonu laarin awon orisirisi eeyan to n’ifee si oro kee-kee-kee ati oro nlala to wa ninu ise ti Fagunwa gbe kale.